Ní ọjọ́rú, Wẹside, ọjọ́ kẹjọ, osù kẹrin, ọdún 2026, fídíò kan tí Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́, ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, ti ń ṣàpèjúwe ìjọba àpapọ̀ bíi “àwọn ènìyàn tí wọ́n kò kún ojú òṣùwọ̀n láti se ìjọba”, tí ó sì ń sọ fún àwọn ènìyàn pé kí wọ́n má dìbó ní ìgbà kejì fún àwọn aláìmọ̀kan yìí ti jáde lórí àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise orí ayélujára.
Lára àwọn ènìyàn tí wọ́n ń lo àwọn ohun ìgbàlódé íbaraẹnise yìí tí wọ́n fi fidio yìí síta sọ pé Ọbásanjọ́ ń bá ìjọba ààrẹ Bọlá Tinubu wí.
Tunde Ednut, gbajúmọ̀ ọmọ Nàìjíríà kan tó máa ń fi àwọn ọ̀rọ̀ sórí ayélujára, fi ẹ̀yà (version) fídíò yìí sí ibi íbaraẹnise rẹ̀ lórí Instagram, ohun ìgbàlódé íbaraẹnisọrẹ orí ayélujára tí àwọn ènìyàn máa ń fi àwòrán tàbí fídíò sí. Àwọn ènìyàn mílíọ̀nù márùn-ún ló ń tẹ̀lé arákùnrin yìí lórí Instagram. Ọ̀rọ̀ yìí wà ní ìpamọ́ níbí.
Nínú ẹ̀yà fídíò yìí tí ó fi síta, wọ́n gbé àwòrán Tinubu sórí nkan ní abẹ́lẹ̀.
Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì ni wọ́n pín ọ̀rọ̀ yìí lórí Instagram, èyí tí ó ní àkòrí tó sọ pé “Hmmmmm!!!”. Àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mọkandinlọgbọn ni wọ́n fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹgbẹ̀rin ni wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún kan àti ẹẹdẹgbẹrin ni wọ́n pín in.
Àwọn ènìyàn kan tún fi ẹ̀yà ọ̀rọ̀ yìí mìíràn síta lórí X, ohun ìgbàlódé íbaraẹnise alámì krọọsi orí ayélujára tó tọ́ka sí Tinubu.
Ẹnì kan tí ó ń lo X tó ń jẹ́ @ejykmykel1, fi fídíò yìí síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “Ọlọ́lá jùlọ Olúṣẹ́gun Àrẹ̀mú Ọbásanjọ́. O sọ ọ̀rọ̀ yìí dáadáa. Ẹgbẹ́ òsèlú APC kò ní fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí,” báyìí ni ọ̀rọ̀ yìí se sọ.
Àwọn ènìyàn ti pín ọ̀rọ̀ yìí lórí X ni ọ̀nà ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹẹdẹgbẹrin-un, àwọn ènìyàn ọgọ́jọ ni wọn fi sọ̀rọ̀ sọ, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti ẹẹdẹgbẹrun-un ló fẹ́ràn ọ̀rọ̀ yìí, àwọn ènìyàn ẹgbẹ̀rin àti ọgọ́ta ó dín márùn-ún ló fi ọ̀rọ̀ yìí pamọ́.
Ẹlòmíràn tó ń lo X, tó ń jẹ́ @ukocarter, fi fídíò yìí síta pẹ̀lú àkòrí tó sọ pé: “Tinubu ti kùnà. Àìmọse rẹ̀ ti mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ajé kùnà. Ẹ má jẹ́ kó padà se ìjọba ni igba kejì” – OBJ.”
ÀYẸ̀WÒ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ TÍ CABLECHECK SE RÈÉ
Nígbà tí CableCheck, ti TheCable Newspaper, ìwé ìròyìn orí ayélujára, se àyẹ̀wò fídíò yìí, a ríi pé Ọbásanjọ́ kò dárúkọ Tinubu nínú fídíò yìí.
Àyẹ̀wò fídíò yìí tí a se pẹ̀lú Google fi hàn pé fídíò yìí ti wà lórí ayélujára láti osù kẹrin, ọdún 2018.
Wọ́n fi fídíò yìí síbí, síbí àti síbí, ní ọdún 2018.
Àwọn ilé isẹ́ ìròyìn tí wọ́n seé gbàgbọ́ bíi TheCable, Channels Television, àti Punch fi ìròyìn síta nípa ọ̀rọ̀ Ọbásanjọ́ yìí ní ọjọ́ kejì, osù kẹrin, ọdún 2018.
Wọ́n se fídíò yìí nígbà tí Ọbásanjọ́ gba àwọn ọmọ ẹgbẹ́ kan tí wọ́n ń pè ní New Nigeria ni àlejò ni Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ Presidential Library, ní Abẹ́òkúta, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ògùn.
Ọbásanjọ́ bá ìjọba Muhammad Buhari, ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, tó se ìjọba láti ọdún 2015 sí ọdún 2023 tẹ́lẹ̀ wí. Ọbásanjọ́ ni pé àìmọ ìjọba se lo jẹ́ kí àwọn ènìyàn jẹ ìyà nígbà ìjọba Buhari.
Kí Ọbásanjọ́ tó sọ̀rọ̀ yìí ní osù kẹrin, ọdún 2018, ó sọ fún Buhari nínú lẹta tí ó kọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà rí pé kó gbàgbé pé ó fẹ́ díje láti se ààrẹ ni ìgbà keji nítorí pé kò mọ̀ọ̀ se.
BÍ CABLECHECK SE RÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ SÍ RÈÉ
Ọdún 2018 ni Ọbásanjọ́ sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà ìjọba Buhari. Kìí se ìgbà ìjọba Tinubu ló sọọ́.
Leave a Reply